Isedale Abinibi Wa

I am Bùkọ́lá R. Adélékè
An Anthropologist
Òǹkọ̀wé Aláàfin Àjàká, Ìgba Tìrẹ Rèé & Olóòótọ́ kò ní kú sí ipò ìkà


Isedale Abinibi Wa

Ẹ kú Ojúlọ́nà ÌTÀN ILÉ DÉLÉSOLÚ NÍ ÒJÉ ÀTI ÌBÁṢEPỌ̀ TÍ WỌ́N NÍ PẸ̀LÚ Ọ̀NÌ láti ẹnu Olóyè Raufu Yesufu tí wọ́n jẹ́ Mọ́gàjí ilé Délésolú àti Ayingun Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn.

#history
#historical
#historichomes
#ibadan
#crocodile

2 years ago | [YT] | 6

Isedale Abinibi Wa

Ẹ KÚ ÌBẸ̀RẸ̀ SÁÀ Ẹ̀KỌ́ 2023 /2024
Gbogbo wa ní ilé iṣẹ́ Ìṣẹ̀dálẹ̀ Media Concept tí a jẹ́ Ìṣẹ̀dálẹ̀ Abínibí Wa ń fi àsìkò yìí kí gbogbo Olùkọ́, akẹ́kọ̀ọ́ àti Òbí kú ìwọlé padà sí ilé-ẹ̀kọ́ lẹ́yìn ìsinmi ìparí sáà ètò ẹ̀kọ́ tó kọjá. Àdúrà wa fún un yín ni pé:
Ẹ̀yin Olùkọ́, Olódùmarè yóò wà pẹ̀lú yín nínú ohun gbogbo tí ẹ ó máa ṣe nínú sáà ètò ẹ̀kọ́ titun yìí. 🙏
Ẹ̀yin Akẹ́kọ̀ọ́, Ọlọ́run yóò fún un yín ní Ọgbọ́n, ìmọ̀ àti Òye láti lè ṣe àṣeyọrí ní sáà ètò ẹ̀kọ́ titun yìí. 🙏
Ẹ̀yin Òbí, Adẹ́dàá yóò ṣílẹ̀kùn àgbọ́nàìgbẹ ìbùkún fún un yín láti rówó ṣe gbogbo ojúṣe yín bí ó ti tọ́ lórí àwọn ọmọ yín ní sáà ètò ẹ̀kọ́ titun yìí. 🙏
Ẹ káàbọ̀ sí sáà ètò ẹ̀kọ́ 2023 /2024🍾🍾🍾🍾🍾🍾🍾🍾

©Bùkọ́lá R. Adélékè, Adégbolá
(Ìṣẹ̀dálẹ̀ Media Concept)

2 years ago | [YT] | 6

Isedale Abinibi Wa

Ẹ JẸ́ KÍ Á JỌ BÁ ALÁYÉLÚWÀ, AWÙJALẸ̀ ÌJẸ̀BÚ YAYỌ̀ ÌPÉ ỌDÚN MẸ́TÀLÉLỌ́GỌ́TA (63) LÓRÍ ÀPÈRÈ

Àkọsílẹ̀ fi hàn pé ní ọjọ́ kejì, oṣù kẹrin ọdún 1960 ni Aláyélúwà, Ọba (Dr) Sikiru Káyọ̀dé, Adétọ̀nà Ọ̀gbágbá ll, gorí àpèrè gẹ́gẹ́ bíi Awùjalẹ̀ karùndínlọ́gọ́ta ní ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Gbogbo wa nílé iṣẹ́ Ìṣẹ̀dálẹ̀ Media Concept náà fi ìkíni wa ránṣẹ́ sí kábíyèsí, Awùjalẹ̀ àti gbogbo Ìjẹ̀bú;

Ìjẹ̀bú ọmọ alárẹ̀,
Ọmọ arójò joyè,
Ọmọ alágẹmọ mẹ́rìndínlógún,
Ọmọ aladìyẹ ògògòmógà,
Ọmọ adìyẹ bàlókùn,
Ara ò rokùn,
Ara ò radìyẹ,
Ọmọ ohun ṣéní,
Ọ̀yọ̀yọ̀ má yọ̀ mọ́ ohun ṣéní,
olèpani, ọmọ dúdú ilé kò mọbelẹ̀ é ṣe níJósí,
Ọmọ moreye mamaroko, morokotan ẹyẹ mátìlo,
Ọmọ mo ní isunle mamalobe,
ọbẹ̀ tin be nílé kò mọ ilé baba tó bí wọn lọmọ,
Ọmọ onígbò ma’de,
Ọmọ onígbò mawo mawo,
Ọmọ onígbò ajoji má gbọdọ̀wọ̀,
Àjòjì tó bá wọ gbórò yóò dẹbọra nílé baba tó bí wọn lọ́mọ.
Ìjẹ̀bú ọmọ èrè níwà,
Ọmọ olówó ìṣèmbáyé,
Òrìsà jẹ́ ń dàbí onílé yí,
kẹ̀lẹ̀bẹ̀ Ìjẹ̀bú owó,
ìtọ̀ Ìjẹ̀bú owó ,
Dúdú Ìjẹ̀bú owó ,
Pupa Ìjẹ̀bú owó,
Kékeré Ìjẹ̀bú owó ,
Àgbà Ìjẹ̀bú owó.
Ìjẹ̀bú Òde Ìjẹ̀bú ni,
Ìjẹ̀bú Igbó Ìjẹ̀bú ni,
Ìjẹ̀bú Ìṣarà Ìjẹ̀bú ni,
Ayépé Ìjẹ̀bú,
Ikorodu Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ní ṣe,
Ìjẹ̀bú Ọmọ oní Ilé ńlá ,
Ìjẹ̀bú Ọmọ aláṣọ ńlá.
Aláyélúwà, ẹṣin ọba á túbọ̀ jeko pẹ́ ooooooo.🙏

©Bùkọ́lá R. Adélékè, Adégbolá
Ìṣẹ̀dálẹ̀ Media Concept (Ìṣẹ̀dálẹ̀ Abínibí Wa)

3 years ago | [YT] | 3

Isedale Abinibi Wa

Ìgbà laṣọ
Ìgbà lèṣo
Ìgbà lọ̀gbìn
Oṣù titun tó lé ní Nàìjíríà yìí,
Ìgbà Ire
Ìgbà ìrọ̀rùn
Ìgbà ìlọsíwájú
Ní á jẹ́ fún wa bó ti wù kó rí 🙏

©‪@isedaleabinibiwa2020‬

3 years ago | [YT] | 8

Isedale Abinibi Wa

“Dan Dan l’owó orí jẹ́

Dan Dan l’owó orí jẹ́

Túláàsì laṣọ ìbora

Owó Orí la fi kọ́ Màpó”

Ǹjẹ́ ẹ rántí ìṣẹ̀lẹ̀ tí orin yìí bí láàárín ọdún 1968-1969 jákèjádò Gúsù ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà? Ẹ jẹ́ á rántí ogun ÀGBẸ́KỌ̀YÀ ká jíròrò lórí okùnfà Ogun náà, ọ̀nà tí wọ́n gbà jà á àti àyọrísí rẹ̀.
Ẹ pàdé èmi àti Alàgbà Gbémisóyè Àmàó lójúkojú (live) lójú òpó Facebook ; www.facebook.com/olukoationkoweyoruba?mibextid=ZbW…

Ní déédéé aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ òní (16/2/2023)

Ẹ kú ojú lọ́nà 🔔🔔🔔

3 years ago | [YT] | 0

Isedale Abinibi Wa

Last year @Ofiki

3 years ago | [YT] | 0

Isedale Abinibi Wa

Isagun 2022: Celebration of Culture, Owa Ooye visited Aworogun Compound today.

3 years ago | [YT] | 3

Isedale Abinibi Wa

Ọjọ́bọ̀ Ọ̀sẹ̀ yìí la ó fi fọ́nrán orin yìí sí ojú táyé níbí láti ṣe àmì àyẹyẹ Oríkádún Aláṣẹ àti Olùdarí ilé iṣẹ́ Ìṣẹ̀dálẹ̀ Media Concept tí ó kọ orin yìí.
A mọyì gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti gbọ́ orin yìí lójú òpó

audiomack.com/bukola-r-adeleke/song/wura-mi-mp3

3 years ago | [YT] | 7

Isedale Abinibi Wa

Ẹ kú ọdún o. Tàmọ́dún á bá wa ní ipò tó dára ju èyí tí a wà lákòókò yìí lọ lágbára Ọlọ́run. 🙏🙏🙏

4 years ago | [YT] | 5

Isedale Abinibi Wa

A kú Ìmúra àyájọ́ ọjọ́ Àṣà ní àgbáyé èyí tí tọdún yìí yóò wáyé ní Ọ̀la, ọjọ́ kọkànlélógún oṣù karùn-ún (21/5/2022).
Bàbá wa, Àràbà Ifáyẹmí Ẹlẹ́buìbọn ni akọni Àṣà pàtàkì tí ẹ ó ní àǹfààní láti pàdé lórí ìkànnì yìí lọ́la.

Ẹ kú ojú lọ́nà 👍

4 years ago | [YT] | 4